Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 8

Ẹ bá wá yin Olúwa, Alelúyà!

1

Ẹni t'Ó f'ọ̀run sílẹ̀ t'Ó wá s'áyé,

Láti kú fún ẹ̀ṣẹ̀ aráyé gbogbo;

Ẹ kọrin Alelúyà s'Ọba mímọ́

Ẹni bá mọ̀'re Jésù k'ó bá wá gbégbè.

CHORUS

Ẹ bá wá yin Olúwa, Alelúyà!

Ẹni bá mọ̀'re Jésù k'ó bá wá gbégbè,

Ẹ bá wá yin Olúwa, Alelúyà!

Ẹni bá mọ̀'re Jésù k'ó bá wá gbégbè

Ẹni bá mọ̀'re Rẹ̀ k'ó bá wá gbégbè

Ẹni bá mọ̀'re Rẹ̀ k'ó bá wá gbégbè

Ẹ bá wá yin Olúwa, Alelúyà!

Ẹni bá mọ̀'re Jésù k'ó bá wá gbégbè.

2

Ẹni t'Ó npà wá mọ́ o, lójojúmọ́,

Ẹni t'Ó nyọ wá nínú ewu gbogbo,

Ẹni t'Ó npà Ísírẹ́lì mọ́ k'ítòògbé;

Ẹni bá mọ̀'re Jésù k'ó bá wá gbégbè.

3

Ẹni t'Ó npèsè fún àìní wá l'áyé,

Ẹni t'Ó nṣoore fún wá l'ọjọ́ gbogbo,

Oore t'Ó nṣe fún wá kò l'óǹkà rárá;

Ẹni bá mọ̀'re Jésù k'ó bá wá gbégbè.

Àmín.